Ákí bísọ́bù sọ wípé kí ìjọba àpapọ̀ ìlú Ajíríyà máa yọ ìdáméwàá kúrò nínú owó osù àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kí wọn tó san ọwó oṣù.
Hmmmm. Orísìíríṣìí, ìyàwó elégún; bí a ṣe ń rí gígùn là ń rí kúkúrú; bí a ṣe ń rí tínrín là ń rí ọ̀rọ̀bọ̀; bí a ṣe ń rí gíga ni à ń rí kúkúrú, nítorípé ijó ni egún fi fẹ́ wọ́n.
Bẹ́ẹ̀ni ìjọba Ajíríyà ṣe ra ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìránṣẹ́ ọlọ́run tí wọ́n wá di ìránsé àwọn ọ̀jẹ̀lú lokaṣan 419.
Ẹ jẹ́ kín rán yín létí ní ìgbà ìdìbò ọdún 2023 tí ó kọjá.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni bàbá abirùn, àrẹ lokaṣion 419 rán aṣọ bíṣọ́bù sí lọ́rùn tí wọ́n sì wọ̀ọ́ wá sí ibití wọ́n ti di ìbò.
Ṣé a rántí pé wọ́n rán aṣọ bíṣọ́bù sí ofarétẹ́dì lọ́rùn ní kotonú.
Àwọn tí wón fi owó rán ńkọ́? tí wọ́n ń bá àwọn ọ̀jẹ̀lú Ajíríyà kó owó lọ sí òkè òkun gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́ láti inú ẹ̀rọ ayélujára.
Ṣe bí tí a bá ń pe ènìyàn ní abìfun raìraì, ṣé kò yẹ kíó pa ìfun rẹ̀ mọ́?
Ṣùgbọ́n bí ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ìlú Ajíríyà kọ́. ǹjẹ́ Ákí bísọ́bù kò ha ti fihàn wípé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, haaa, kí ló kan ìjọba Ajíríyà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìdámẹ́wàá?
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní ìránṣé ọlọ́run ni ebíléndé, aláìríṣẹ́ṣe, a fi ọ̀rọ̀ ẹ̀taǹ gba owó lọ́wọ́ ènìyàn nípa ìríran tó ba ni lẹ́rù, àsọtẹ́lẹ̀ èké tó sọ ẹnití gbọ́ọ di aláìní ìfọ̀kànbalẹ̀, tí ó sì sá kíjokíjo lọ sí ọ̀dọ̀ wọn fún àbò níbi tí kòti sí àbò.
Bísọ́bù kò lè ṣe aláìsọ bẹ́ẹ̀, owó ti gbẹ ní àpò àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀, lóṣe rárí wọ inú agbo àwọn ọ̀jẹ̀lú ìjọba lokasan 419 lọ. ǹ jẹ́ èyí kò wá jẹ́ ìtìjú fún Ákí Bísọ́bù, odidi Ákí Bísọ́bù, ló sọ èyí jáde sí ìgboro ayé. Òùn nìkan kọ́ o, wọ́n pọ̀ jáǹtìrẹrẹ ní ìlú Ajíríyà.
Nítorí ìdí èyí, ẹ jẹ́ kí àwa ọmọ IYP orílẹ̀ èdè olómìnira máa kíyèsára nítorí àwọn ẹlẹ́tàn bí èyí, níwọ̀n ba ọjọ́ péréte tí ó kù kí ìjọba Yorùbá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àkóso ní pẹrẹwu lórí ilẹ̀ olómìnira DRY.
- Ilé Ẹjọ́ Ìgbẹ́jọ́ Ìwà Ọ̀daràn Ní Àgbáyé Dá Ọ̀kan Nínú Àwọn Olórí Agbésùnmọ̀mí Lẹ́bi
- Orílẹ̀-Èdè Mẹ́wa Fi Aṣ’ojú Wọn Rán’ṣẹ́ Sí Burkina Faso
- Ojú Ìwòye afọ́-ọ̀rọ̀-sí-wẹ́wẹ́ Kan nípa ọ̀rọ̀ ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ ní ilẹ̀ Yorùbá.
- Ìkìlọ̀ Pàtàkí Lórí Irúgbìn GMO
- OWÓ DỌ́LÀ AMERIKA JẸ́ OHUN ÌJÀ OLÓRÓ FÚN ÌJẸGÀBA LÓRÍ ÀGBÁYÉ
Àwọn kẹ̀, níbo? Kò sáyè fún wọn ní ilẹ̀ abínibí Yorùbá IYP fún irú àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀jẹ̀lú ìlú Ajíríyà, àwọn wọ̀bià, ọ̀dájú Ákí Bísọ́bù, àwọn ìran wòlíì Bálámù nínú Bíbélì. Ìṣiwèrè wọn ìlú ajíríyà náà ló máa mọ.